Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Job 25 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Ìdáhùn Bilidadi

1Nígbà náà ní Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn wí pé,

2“Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀,òun ní i ṣe ìlàjà ní ibi gíga gíga ọ̀run.

3Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí,tàbí ara ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí?

4Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run?Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́?

5Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀,àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀,

6kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin,àti ọmọ ènìyàn tí í ṣe kòkòrò!”

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]