Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Job 26 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Ìdáhùn Jobu

1Ṣùgbọ́n Jobu sì dáhùn wí pé,

2“Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tí kò ní ipá,báwo ní ìwọ ń ṣe gbe apá ẹni tí kò ní agbára?

3Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ fun ẹni tí kò ní ọgbọ́n,tàbí báwo òye rẹ to pọ to bẹ́ẹ̀?

4Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,àti ẹ̀mí ta ni ó gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀?”

5“Àwọn aláìlágbára ti isà òkú wárìrì,lábẹ́ omi pẹ̀lú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

6Ìhòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run,ibi ìparun kò sí ní ibojì.

7Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfúrufú,ó sì so ayé rọ̀ ní ojú asán.

8Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn;àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn.

9Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn,ó sì tẹ àwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí.

10Ó fi ìdè yí omi òkun ká,títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.

11Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì,ẹnu sì yà wọ́n sì ìbáwí rẹ̀.

12Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi Òkun;nípa òye rẹ̀, ó gé agbéraga sí wẹ́wẹ́.

13Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́;ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ejò wíwọ́ nì.

14Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀;ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó!Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]