Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Isaiah 12 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Orin ìyìn

1Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé,“Èmi ó yìn ọ́, Olúwa.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí miìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀ìwọ sì ti tù mí nínú.

2Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù.Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,òun ti di ìgbàlà mi.”

3Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omiláti inú kànga ìgbàlà.

4Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé,“Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,ohun tí ó ti ṣekí o sì kéde pé a ti gbéorúkọ rẹ̀ ga.

5Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.

6Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni,nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣoti Israẹli láàrín yín.”

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]