Side by side with the Father's Heart Bible™ Saamu ti Dafidi.
1Olúwa ni olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
2Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù,Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́,
3Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò.Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodonítorí orúkọ rẹ̀.
4Bí mo tilẹ̀ ń rìnláàrín àfonífojì òjìji ikú,èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan,nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ,wọ́n ń tù mí nínú.
5Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú miní ojú àwọn ọ̀tá à mi.Ìwọ ta òróró sí mi ní orí;ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
6Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìnní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwatítí láéláé.