Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 24 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Ti Dafidi. Saamu.

1Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀,ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;

2nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkunó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

3Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ?Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?

4Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asántí kò sì búra èké.

5Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.

6Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀,tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.

7Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà;kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé!Kí ọba ògo le è wọlé.

8Ta ni ọba ògo náà?Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le,Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.

9Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà;kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,kí Ọba ògo le è wọlé wá.

10Ta ni Ọba ògo náà?Olúwa àwọn ọmọ-ogunÒun ni Ọba ògo náà. Sela.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]