Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 12 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.

1Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa, nítorí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kò sí mọ́;olóòtítọ́ tí pòórá kúrò láàrín àwọn ènìyàn.

2Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀;ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn.

3Kí Olúwa kí ó gé ètè èké wọnàti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu

4tí ó wí pé,“Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa;àwa ní ètè wa, ta ni ọ̀gá wa?”

5“Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní,Èmi yóò dìde nísinsin yìí,” ni Olúwa wí.“Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.”

6Ọ̀rọ̀ Olúwa sì jẹ aláìlábùkù,gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀,tí a sọ di mímọ́ nígbà méje.

7Olúwa, ìwọ yóò pa wá mọ́kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé.

8Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kirinígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òsì láàrín àwọn ènìyàn.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]