Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 13 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé?Yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?

2Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà,àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi?Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi?

3Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, Olúwa Ọlọ́run mi.Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú.

4Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,”àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.

5Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà;ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.

6Èmi ó máa kọrin sí Olúwa,nítorí ó dára sí mi.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]