Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 11 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Fún adarí orin. Ti Dafidi.

1Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa.Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé,“Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ.

2Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀;wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùnláti tafà níbi òjìjisí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin.

3Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́kí ni olódodo yóò ṣe?”

4Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.

5Olúwa ń yẹ olódodo wò,ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipáni ọkàn rẹ̀ kórìíra.

6Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jòẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó;àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.

7Nítorí, olódodo ní Olúwa,o fẹ́ràn òdodo;ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]