Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 142 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà.

1Èmi kígbe sókè sí Olúwa;èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.

2Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.

3Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi,ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìnènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀.

4Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì ikò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mièmi kò ní ààbò;kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.

5Èmi kígbe sí ọ, Olúwa:èmi wí pé, “Ìwọ ni ààbò mi,ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”

6Fi etí sí igbe mi,nítorí tí èmi wà nínú àìnírètígbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi,nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ.

7Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú,kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ.Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkirinítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]