Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 1 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ

1Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.

2Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwaàti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.

3Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

4Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkàtí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.

5Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.

6Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]