Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 2 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

1Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀,àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?

2Àwọn ọba ayé péjọpọ̀àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀sí Olúwa àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.

3Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”

4Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín;Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.

5Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,

6“Èmi ti fi ọba mi sí ipòlórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”

7Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;lónìí, èmi ti di baba rẹ.

8Béèrè lọ́wọ́ mi,Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ,òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.

9Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọnìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”

10Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n;ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.

11Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rùẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.

12Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú,kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín,nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan.Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]