Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 15 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Saamu ti Dafidi.

1Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ?Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?

2Ẹni tí ń rìn déédétí ó sì ń sọ òtítọ́,láti inú ọkàn rẹ̀;

3tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,

4ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígànṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀àní tí kò sì yípadà,

5tí ó ń yá ni lówó láìsí èlétí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀.Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyíni a kì yóò mì láéláé.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]