Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 20 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú;kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.

2Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.

3Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹkí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela.

4Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹkí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ.

5Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gunàwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.Kí Olúwa kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.

6Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé,Olúwa pa ẹni àmì òróró rẹ̀ mọ́.Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wápẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.

7Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin,ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.

8Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú,ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.

9Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba!Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]