Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 21 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ,àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!

2Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un,bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. Sela.

3Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nàìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.

4Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un,àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.

5Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un;ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.

6Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un:ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.

7Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa;nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnàkì yóò sípò padà.

8Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí;ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.

9Nígbà tí ìwọ bá yọìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru.Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀,àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.

10Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀,àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.

11Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọwọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.

12Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padànígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.

13Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ;a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]