Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 19 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

2Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.

3Kò sí ohùn tàbí èdèníbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn.

4Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé,ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé.Ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.

5Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá,òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje.

6Ìjáde lọ rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wáàti àyíká rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ rẹ̀;kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore rẹ̀.

7Pípé ni òfin Olúwa,ó ń yí ọkàn padà.Ẹ̀rí Olúwa dánilójú,ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.

8Ìlànà Olúwa tọ̀nà,ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.Àṣẹ Olúwa ni mímọ́,ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.

9Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́,ó ń faradà títí láéláé.Ìdájọ́ Olúwa dájúòdodo ni gbogbo wọn.

10Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ,ju wúrà tí o dára jùlọ,wọ́n dùn ju oyin lọ,àti ju afárá oyin lọ.

11Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí;nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.

12Ta ni ó lè mọ àṣìṣe rẹ̀?Dáríjì mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.

13Wẹ ìránṣẹ́ rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá;má ṣe jẹ kí wọn kí ó jẹ ọba lórí mi.Nígbà náà ní èmi yóò dúró ṣinṣin,èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

14Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mikí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,Ìwọ Olúwa àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]