Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 149 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa.Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

2Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá ajẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó níayọ̀ nínú ọba wọn.

3Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.

4Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.

5Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.

6Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọnàti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn.

7Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,

8láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọnàti láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀irin de àwọn ọlọ́lá wọn.

9Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọnèyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]