Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Isaiah 15 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Moabu

1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu,a pa Ari run ní Moabu,òru kan ní a pa á run!A pa Kiri run ní Moabu,òru kan ní a pa á run!

2Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀,sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún,Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba.Gbogbo orí ni a fágbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù.

3Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà,ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú.Wọ́n pohùnréré,wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.

4Heṣboni àti Eleale ké sóde,ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi.Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbetí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.

5Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu;àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari,títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi.Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhitiwọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ,ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimuwọ́n ń pohùnréré ìparun wọn.

6Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹàwọn koríko sì ti gbẹ,gbogbo ewéko ti tánewé tútù kankan kò sí mọ́.

7Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní tí wọ́n sì tò jọwọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ odò Poplari.

8Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu;ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu,igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu.

9Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀,síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni—kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabuàti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]