Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 137 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

1Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòóàwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.

2Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò,tí ó wà láàrín rẹ̀.

3Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọntí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa,àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá;wọn wí pé, “Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa!”

4Àwa ó ti ṣe kọ orinOlúwa ní ilẹ̀ àjèjì

5Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹjẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.

6Bí èmi kò bá rántí rẹ,jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájúolórí ayọ̀ mi gbogbo.

7Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu,lára àwọn ọmọ Edomu,àwọn ẹni tí ń wí pé,“Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”

8Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun;ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọbí ìwọ ti rò sí wa.

9Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹtí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]