Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Jeremiah 47 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Àṣọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ará Filistini

1Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tó tọ wòlíì Jeremiah wá nípa àwọn Filistini, kí ó tó di pé Farao dojúkọ Gasa.

2Báyìí ni Olúwa wí:“Wo bí omi ti ń ru sókè ní àríwá,wọn ó di odò tí ń bo bèbè mọ́lẹ̀.Wọn kò ní borí ilẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà lórí rẹ̀,ìlú àti àwọn tó ń gbé nínú wọn.Àwọn ènìyàn yóò kígbe,gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà yóò hu

3nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìró títẹ̀lé pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin alágbáranígbà tí wọ́n bá gbọ́ ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ọ̀tá ńláàti iye kẹ̀kẹ́ wọn.Àwọn baba kò ní lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́;ọwọ́ wọn yóò kákò.

4Nítorí tí ọjọ́ náà ti péláti pa àwọn Filistini run,kí a sì mú àwọn tí ó làtí ó lè ran Tire àti Sidoni lọ́wọ́ kúrò.Olúwa ti ṣetán láti pa Filistini run,àwọn tí ó kù ní agbègbè Kafitori.

5Gasa yóò fá irun orí rẹ̀ nínú ọ̀fọ̀.A ó pa Aṣkeloni lẹ́nu mọ́;ìyókù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀,ìwọ yóò ti sá ara rẹ lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?

6“Ẹ̀yin kígbe, ‘Yé è, idà Olúwa,yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò sinmi?Padà sínú àkọ̀ rẹ;sinmi kí o sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.’

7Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe sinmi,nígbà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un,nígbà tí ó ti pa á láṣẹláti dojúkọ Aṣkeloni àti agbègbè rẹ̀.”

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]