Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 146 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.Fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

2Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mi,èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè.

3Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé,àní, ọmọ ènìyàn,lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.

4Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀,ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo.

5Ìbùkún ni fún ẹni tíỌlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀tí ìrètí rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

6Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé,òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn,ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé.

7Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára,tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa,Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀,

8Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran,Olúwa, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga,Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo.

9Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejòó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó síṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

10Olúwa jẹ ọba títí láé;Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]