Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 145 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Saamu ìyìn. Ti Dafidi.

1Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi;èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé.

2Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé.

3Títóbi ni Olúwa. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀:kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀.

4Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn;wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ.

5Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo,èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ.

6Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rùèmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀.

7Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ.

8Olóore-ọ̀fẹ́ ni Olúwa àti aláàánúó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀.

9Olúwa dára sí ẹni gbogbo;ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá.

10Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá niyóò máa yìn ọ́ Olúwa;àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ.

11Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹwọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ,

12kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo.

13Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni,àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran.

14Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú róó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.

15Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́,ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ.

16Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.

17Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.

18Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.

19Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ;ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.

20Olúwa dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ síṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹnibúburú ní yóò parun.

21Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn Olúwa.Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]