Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Psalms 9 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Fún adarí orin. Ní ti ohun orin. “Ní ti ikú ọmọ.” Saamu ti Dafidi.

1Èmi ó yìn ọ́, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo.

2Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ;èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.

3Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà;wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ.

4Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú;ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.

5Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run;Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.

6Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá,ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu;àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé.

7Olúwa jẹ ọba títí láé;ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.

8Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo;yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.

9Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.

10Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ,nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.

11Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni;kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe.

12Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí;òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.

13Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi!Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,

14kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioniàti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.

15Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́;ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.

16A mọ Olúwa nípa òdodo rẹ̀;àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

17Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú,àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.

18Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé,ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.

19Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí;jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ.

20Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa;jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]