Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 13 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

1Ọlọ́gbọ́n ọmọ gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀,ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò gbọ́ ìbáwí.

2Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn ohun rere,ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ọkàn aláìṣòótọ́ ní ìwà ipá.

3Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́,ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù gbàù yóò parun.

4Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkan kan,ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣe ọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn.

5Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́,ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú.

6Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú,ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò.

7Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkan kanẹlòmíràn díbọ́n bí i tálákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

8Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà.

9Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro,ṣùgbọ́n fìtílà ènìyàn búburú ni a pa kú.

10Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ niṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.

11Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ,ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i.

12Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.

13Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.

14Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè,tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú.

15Òye pípé ń mú ni rí ojúrere,ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìṣòótọ́ kì í tọ́jọ́.

16Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀,ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.

17Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdààmúṣùgbọ́n aṣojú olóòtítọ́ mú ìwòsàn wá.

18Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú,ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.

19Ìfẹ́ tí a mú ṣẹ dùn mọ́ ọkànṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.

20Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́nṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.

21Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀,ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.

22Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.

23Ilẹ̀ ẹ tálákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìre oko wáṣùgbọ́n àìṣòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.

24Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa bá a wí.

25Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùnṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]