Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 13 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 A wise son heeds his father's instruction, but a scoffer does not listen to rebuke. Ọlọ́gbọ́n ọmọ gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò gbọ́ ìbáwí.
2 From the fruit of his mouth a person enjoys good things, but the appetite of the treacherous is for violence. Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn ohun rere, ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ọkàn aláìṣòótọ́ ní ìwà ipá.
3 Whoever guards his mouth protects his life, but one who opens his lips wide comes to ruin. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù gbàù yóò parun.
4 The lazy person craves and gets nothing, but the appetite of the diligent is richly satisfied. Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkan kan, ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣe ọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn.
5 The righteous hates falsehood, but the wicked brings shame and disgrace. Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú.
6 Righteousness guards the one whose way is blameless, but wickedness overthrows the sinner. Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú, ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò.
7 One person pretends to be rich, yet has nothing; another pretends to be poor, yet has great wealth. Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkan kan ẹlòmíràn díbọ́n bí i tálákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
8 A person's wealth may ransom his life, but the poor hears no threat. Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀ ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà.
9 The light of the righteous shines joyfully, but the lamp of the wicked will be snuffed out. Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro, ṣùgbọ́n fìtílà ènìyàn búburú ni a pa kú.
10 Arrogance breeds nothing but strife, but wisdom is with those who seek advice. Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.
11 Wealth gained by fraud dwindles away, but whoever gathers little by little makes it grow. Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i.
12 Hope deferred makes the heart sick, but desire fulfilled is a tree of life. Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀ ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.
13 Whoever despises the word brings ruin on himself, but the one who reveres the commandment will be rewarded. Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.
14 The teaching of the wise is a fountain of life, turning a person away from the snares of death. Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú.
15 Good sense wins favor, but the way of the treacherous is their undoing. Òye pípé ń mú ni rí ojúrere, ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìṣòótọ́ kì í tọ́jọ́.
16 Every prudent person acts with knowledge, but a fool flaunts his foolishness. Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.
17 A wicked messenger falls into trouble, but a faithful envoy brings healing. Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdààmú ṣùgbọ́n aṣojú olóòtítọ́ mú ìwòsàn wá.
18 Poverty and shame come to whoever ignores discipline, but the one who heeds correction is honored. Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.
19 A desire fulfilled is sweet to the soul, but turning away from evil is detestable to fools. Ìfẹ́ tí a mú ṣẹ dùn mọ́ ọkàn ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.
20 Whoever walks with the wise grows wise, but the companion of fools suffers harm. Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.
21 Disaster pursues sinners, but good rewards the righteous. Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.
22 A good person leaves an inheritance to his grandchildren, but the sinner's wealth is stored up for the righteous. Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.
23 The unplowed field of the poor could yield abundant food, but it is swept away for lack of justice. Ilẹ̀ ẹ tálákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìre oko wá ṣùgbọ́n àìṣòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.
24 Whoever withholds the rod hates his son, but the one who loves him is diligent to discipline him. Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa bá a wí.
25 The righteous eats to his heart's content, but the belly of the wicked goes hungry. Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]