Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Isaiah 56 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Ìgbàlà fún àwọn mìíràn

1Èyí ni ohun ti Olúwa sọ:“Ẹ pa ìdájọ́ mọ́ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà,nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsíàti òdodo mi ni a ó fihàn láìpẹ́ jọjọ.

2Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí,àti fún ọmọ ènìyàn tí ó dìímú ṣinṣin,tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́,tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”

3Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀mọ́ Olúwa sọ wí pé,“Olúwa yóò yà mí sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”Àti kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé,“Igi gbígbẹ lásán ni mí.”

4Nítorí pé báyìí ni Olúwa wí:“Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mití wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin

5fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀ìrántí kan àti orúkọ kantí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin,Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayétí a kì yóò ké kúrò.

6Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ Olúwaláti sìn ín,láti fẹ́ orúkọ Olúwaàti láti foríbalẹ̀ fún ungbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—

7àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi,èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi.Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn,ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi;nítorí a ó máa pe ilé mi níilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”

8Olúwa Olódùmarè sọ wí pé—ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Israẹli jọ:“Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lú wọnyàtọ̀ sí àwọn tí a ti kójọ.”

Ẹ̀sùn tí Ọlọ́run fi kan àwọn ìkà

9Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá,ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run!

10Àwọn olùṣọ́ Israẹli fọ́jú,gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀;gbogbo wọn jẹ́ adití ajá,wọn kò lè gbó;wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá,wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn.

11Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀;wọn kì í ní ànító.Wọ́n jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn tí kò ní òye;olúkúlùkù ń yà ṣọ́nà ara rẹ̀,ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀.

12Igbe ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ni wí pé, “Wá, fún mi ní ọtí wáìnì!Jẹ́ kí a mu ọtí líle wa lámu yóọ̀la yóò sì dàbí òní,tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]