Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 22 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Orúkọ rere sàn ju ọrọ̀ lọ

1Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ,àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.

2Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọpọ̀:Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.

3Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀,ó ṣé ara rẹ̀ mọ́:ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà.

4Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.

5Ègún àti ìdẹ̀kùn ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà:ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn.

6Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀:nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.

7Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú,ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè.

8Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán:ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà.

9Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún;nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú.

10Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde;nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun.

11Ẹni tí ó fẹ́ ìwà funfun ti àyà,tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀.

12Ojú Olúwa pa ìmọ̀ mọ́,ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò.

13Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde!Yóò pa mí ní ìgboro!”

14Ẹnu àwọn àjèjì obìnrin, ihò jíjìn ni;ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀.

15Àyà ọmọdé ni ìwà wèrè dì sí;ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

16Ẹni tó ń ni tálákà lára láti ní ọrọ̀,tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ,yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí.Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n

17Dẹtí rẹ sílẹ̀,kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n,kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi.

18Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ;nígbà tí a sì pèsè wọn tán ní ètè rẹ.

19Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà ní ti Olúwa,èmi fihàn ọ́ lónìí, àní fún ọ.

20Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradárasí ọ ní ti ìmọ̀ràn àti ní ti ẹ̀kọ́,

21kí ó lè mú ọ mọ ìdájú ọ̀rọ̀ òtítọ́;kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́fún àwọn tí ó rán ọ?

22Má ṣe ja tálákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ tálákà:bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè,

23nítorí Olúwa yóò gbèjà wọn,yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.

24Má ṣe bá oníbìínú ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́;má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn.

25Kí ìwọ má ba à kọ́ ìwà rẹ̀, ìwọ a sì gba ìkẹ́kùn fún ara rẹ.

26Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀nwọ́,tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè.

27Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi san,nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹni rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?

28Má ṣe yẹ ààlà ilẹ̀ ìgbàanì,tí àwọn baba rẹ ti pa.

29Ìwọ ha rí ènìyàn tí ó ń fi àìṣe ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀?Òun yóò dúró níwájú àwọn ọba;òun kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]