Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 22 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 A good name is to be chosen rather than great riches, and favor is better than silver or gold. Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ, àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.
2 The rich and the poor meet together; our Father is the Maker of them all. Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọpọ̀: Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.
3 The prudent sees danger and takes cover, but the simple keep going and pay the price. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó ṣé ara rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà.
4 The reward for humility and the fear of our Father is riches and honor and life. Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.
5 Thorns and snares lie in the path of the crooked; whoever guards his soul stays far from them. Ègún àti ìdẹ̀kùn ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà: ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn.
6 Train up a child in the way he should go, and even when he is old he will not depart from it. Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.
7 The rich rules over the poor, and the borrower is slave to the lender. Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú, ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè.
8 Whoever sows injustice will reap calamity, and the rod of his fury will fail. Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán: ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà.
9 Whoever has a generous eye will be blessed, for he shares his bread with the poor. Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún; nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú.
10 Drive out the scoffer, and strife goes with him; quarreling and abuse will cease. Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde; nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun.
11 Whoever loves a pure heart and speaks graciously will have the king as his friend. Ẹni tí ó fẹ́ ìwà funfun ti àyà, tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀.
12 The eyes of our Father keep watch over knowledge, but he overturns the words of the traitor. Ojú Olúwa pa ìmọ̀ mọ́, ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò.
13 The lazy person says, "There is a lion outside! I will be killed in the streets!" Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde! Yóò pa mí ní ìgboro!”
14 The mouth of forbidden women is a deep pit; whoever draws our Father's anger will fall into it. Ẹnu àwọn àjèjì obìnrin, ihò jíjìn ni; ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀.
15 Foolishness is bound up in the heart of a child, but the rod of discipline drives it far away. Àyà ọmọdé ni ìwà wèrè dì sí; ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
16 Whoever oppresses the poor to enrich himself, or gives to the rich, will come only to poverty. Ẹni tó ń ni tálákà lára láti ní ọrọ̀, tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ, yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí. Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.
17 Listen carefully to the words of the wise, and apply your heart to my knowledge, Dẹtí rẹ sílẹ̀, kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n, kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi.
18 for it will be pleasant if you keep them within you, if all of them are ready on your lips. Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ; nígbà tí a sì pèsè wọn tán ní ètè rẹ.
19 So that your trust may be in our Father, I have made them known to you today, even to you. Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà ní ti Olúwa, èmi fihàn ọ́ lónìí, àní fún ọ.
20 Have I not written for you thirty sayings of counsel and knowledge, Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradára sí ọ ní ti ìmọ̀ràn àti ní ti ẹ̀kọ́,
21 to teach you what is right and true, so that you may give a true answer to those who sent you? kí ó lè mú ọ mọ ìdájú ọ̀rọ̀ òtítọ́; kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́ fún àwọn tí ó rán ọ?
22 Do not rob the poor because he is poor, or crush the afflicted at the gate, Má ṣe ja tálákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ tálákà: bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè,
23 for our Father will plead their cause and will rob of life those who rob them. nítorí Olúwa yóò gbèjà wọn, yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.
24 Do not befriend a man given to anger, and do not go with a hot-tempered man, Má ṣe bá oníbìínú ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́; má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn.
25 or you will learn his ways and entangle yourself in a snare. Kí ìwọ má ba à kọ́ ìwà rẹ̀, ìwọ a sì gba ìkẹ́kùn fún ara rẹ.
26 Do not be one of those who give pledges, who put up security for debts. Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀nwọ́, tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè.
27 If you have nothing to pay with, why should your bed be taken from under you? Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi san, nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹni rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?
28 Do not move the ancient boundary stone that your fathers set up. Má ṣe yẹ ààlà ilẹ̀ ìgbàanì, tí àwọn baba rẹ ti pa.
29 Do you see a man skillful in his work? He will stand before kings; he will not stand before ordinary men. Ìwọ ha rí ènìyàn tí ó ń fi àìṣe ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀? Òun yóò dúró níwájú àwọn ọba; òun kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]