Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Isaiah 18 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Kuṣi

1Ègbé ni fún ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́ eṣú,ní àwọn ipadò Kuṣi,

2tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí Òkunlórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi eèsún papirusi ṣe.Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára,sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀ ara wọn jọ̀lọ̀,sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri,orílẹ̀-èdè aláfojúdi alájèjì èdè,tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ.

3Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé,tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé,nígbà tí a bá gbé àsíá kan sókè lórí òkè,ẹ ó rí i,nígbà tí a bá fun fèrè kanẹ ó gbọ́ ọ.

4Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:“Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́, èmi yóò sì máa wo òréréláti ibùgbé e mi wá,gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànṣán oòrùn,gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárín gbùngbùn ìkórè.”

5Nítorí, kí ìkórè tó bẹ̀rẹ̀,nígbà tí ìrudí bá kún,nígbà tí ìtànná bá di èso àjàrà pípọ́n.Òun yóò sì fi dòjé rẹ́ ẹ̀ka tuntun,yóò sì mu kúrò,yóò sì gé ẹ̀ka lulẹ̀.

6A ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ẹyẹ òkè ńláàti fún àwọn ẹranko búburú;àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣe oúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùnàti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò.

7Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún Olúwa àwọn ọmọ-ogunláti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran-ara wọn jọ̀lọ̀,láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo,orílẹ̀-èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè,ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ—a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè Sioni, ibi tí orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbé wà.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]