Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 7 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 My son, keep my words, and store up my commandments within you. Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, sì fi àwọn òfin mi pamọ́ sínú ọkàn rẹ.
2 Keep my commandments and live; guard my teaching as the apple of your eye. Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yè tọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ.
3 Bind them on your fingers; write them on the tablet of your heart. Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹun kọ wọ́n sí inú wàláà àyà rẹ.
4 Say to wisdom, "You are my sister," and call understanding your dearest friend, Wí fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arábìnrin mi,” sì pe òye ní ìbátan rẹ.
5 to keep you from the forbidden woman, from the stranger with her smooth words. Wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè, kúrò lọ́wọ́ àjèjì obìnrin àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀.
6 For at the window of my house I looked down through my lattice, Ní ojú fèrèsé ilé è mi mo wo ìta láti ojú fèrèsé.
7 and I saw among the naive, I noticed among the young men, a youth who lacked sense, Mo rí i láàrín àwọn aláìmọ̀kan mo sì kíyèsi láàrín àwọn ọ̀dọ́kùnrin, ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.
8 passing through the street near her corner, taking the road to her house, Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbèrè obìnrin náà, ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀.
9 in the twilight, as the day faded, in the dark of night and gloom. Ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀, bí òkùnkùn ṣe ń bo ni lára.
10 And there a woman comes to meet him, dressed like a prostitute, with cunning in her heart. Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀, ó múra bí panṣágà pẹ̀lú ètè búburú.
11 She is loud and defiant; her feet will not stay at home. (Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí, ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;
12 Now in the street, now in the squares, she lurks at every corner. bí ó ti ń já níhìn-ín ní ó ń já lọ́hùn ún gbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.)
13 She grabs him and kisses him, and with a brazen face she says to him: Ó dìímú, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu pẹ̀lú ojú díndín ó wí pé,
14 "I had peace offerings to bring; today I have paid my vows. “Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé; lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.
15 So I came out to meet you, to look for you eagerly, and I have found you. Nítorí náà ni n o ṣe jáde wá pàdé è rẹ; mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!
16 I have spread my bed with coverings, with colored linens from Egypt. Mo ti tẹ́ ibùsùn mi pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Ejibiti.
17 I have perfumed my bed with myrrh, aloes, and cinnamon. Mo ti fi nǹkan olóòórùn dídùn sí ibùsùn mi bí i òjìá, aloe àti kinamoni.
18 Come, let us drink deep of love until morning; let us lose ourselves in love. Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀; jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!
19 For my husband is not at home; he has gone on a long journey. Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé; ó ti lọ sí ìrìnàjò jíjìn.
20 He took a bag of money with him and will not come home until the full moon." Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́ kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”
21 With all her persuasive words she sways him; with her smooth lips she draws him in. Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà; ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.
22 All at once he follows her, like an ox going to the slaughter, like a deer stepping into a snare, Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà, bí i màlúù tí ń lọ sí ibi pípa, tàbí bí àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi okùn ìso.
23 until an arrow pierces its liver; like a bird darting into a trap, he does not know it will cost him his life. Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀, bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn, láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.
24 Now then, my sons, listen to me, and pay attention to what I say. Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi fọkàn sí nǹkan tí mo sọ.
25 Do not let your heart turn aside to her ways; do not wander into her paths. Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀, tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.
26 For she has brought down many victims; her slain are a mighty multitude. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀. Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.
27 Her house is the road to the grave, going down to the chambers of death. Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààrà sí isà òkú, tí ó lọ tààrà sí àgbàlá ikú.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]