Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 8 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 Does not Wisdom call out, and understanding raise her voice? Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta? Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?
2 Atop the heights along the way, where the paths meet, she takes her stand. Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, ní ìkóríta, ní ó dúró;
3 Beside the gates, at the entrance to the city, at the doorways she cries aloud: ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú, ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:
4 "To you, all people, I call out; my voice reaches all humanity. “Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè; mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn.
5 You who are simple, learn prudence; you who are foolish, gain an understanding heart. Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n; ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye.
6 Listen, for I speak of noble things, and everything I say is right. Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye; Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́,
7 My mouth utters truth, for my lips detest wickedness. ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́, nítorí ètè mi kórìíra ibi.
8 All the words of my mouth are righteous; none of them is twisted or crooked. Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́, kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀.
9 To the one who understands they are all clear, and right to those who find knowledge. Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà; wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.
10 Take my instruction instead of silver, and knowledge rather than choice gold, Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà, ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,
11 for wisdom is better than jewels, and nothing you desire can compare with her. nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ, kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e.
12 I, Wisdom, dwell with prudence, and I find knowledge and discretion. “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye; mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.
13 The fear of our Father is to hate evil. Pride and arrogance, the evil way, and perverse speech I hate. Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi mo kórìíra ìgbéraga àti agídí, ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
14 Counsel is mine, and sound wisdom; I am understanding; strength is mine. Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi mo ní òye àti agbára.
15 By me kings reign, and rulers decree what is just; Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára.
16 by me princes govern, and nobles—all who rule with justice. Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso, àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.
17 I love those who love me, and those who search for me find me. Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi, àwọn tí ó sì wá mi rí mi.
18 With me are riches and honor, enduring wealth and righteousness. Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà, ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.
19 My fruit is better than gold, than the finest gold, and what I yield surpasses choice silver. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ; ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.
20 I walk in the way of righteousness, along the paths of justice, Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo, ní ojú ọ̀nà òtítọ́,
21 giving wealth as an inheritance to those who love me, and filling their treasuries. mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.
22 Our Father brought me forth at the beginning of his way, before his works of old. “Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀. Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;
23 From ages past I was established, from the beginning, before the earth began. a ti yàn mí láti ayérayé, láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.
24 When there were no deep waters I was brought forth, when there were no springs overflowing with water. Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi, nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú;
25 Before the mountains were settled, before the hills, I was brought forth, kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn, ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,
26 while he had not yet made the earth and its fields, or the first dust of the world. kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀ tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.
27 When he set the heavens in place, I was there; when he drew a circle over the face of the deep, Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn, nígbà tí ó fi òsùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,
28 when he set the skies in place above, when he established the springs of the deep, nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀,
29 when he set for the sea its boundary so the waters would not cross their limits, when he marked out the foundations of the earth, nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀, àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.
30 then I was beside him as a master craftsman, and I was his daily delight, rejoicing before him always, Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́, mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀.
31 rejoicing in his whole world, and delighting in the human family. Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.
32 And now, my children, listen to me: blessed are those who keep my ways. “Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́.
33 Listen to instruction and be wise; do not ignore it. Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n; má ṣe pa á tì sápá kan.
34 Blessed is the one who listens to me, watching daily at my gates, waiting beside my doorway. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi, tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́, tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi.
35 For whoever finds me finds life and receives favor from our Father. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè ó sì rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ Olúwa.
36 But whoever misses me harms his own soul; all who hate me love death." Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára gbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]