Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 8 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Ọgbọ́n n fi ìpè síta

1Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?

2Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà,ní ìkóríta, ní ó dúró;

3ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:

4“Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn.

5Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n;ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye.

6Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye;Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́,

7ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́,nítorí ètè mi kórìíra ibi.

8Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́,kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀.

9Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà;wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.

10Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà,ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,

11nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ,kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e.

12“Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.

13Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibimo kórìíra ìgbéraga àti agídí,ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

14Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmimo ní òye àti agbára.

15Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkósotí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára.

16Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso,àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.

17Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi,àwọn tí ó sì wá mi rí mi.

18Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà,ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.

19Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.

20Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,ní ojú ọ̀nà òtítọ́,

21mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mimo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.

22“Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;

23a ti yàn mí láti ayérayé,láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.

24Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi,nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú;

25kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn,ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,

26kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.

27Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn,nígbà tí ó fi òsùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,

28nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókètí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀,

29nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkunkí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀,àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.

30Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́,mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀.

31Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dámo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.

32“Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi,ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́.

33Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n;má ṣe pa á tì sápá kan.

34Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi,tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́,tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi.

35Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyèó sì rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ Olúwa.

36Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ láragbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]