Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 31 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Àwọn ọ̀rọ̀ ọba Lemueli

1Àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ti Lemueli ọba, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ,

2“Gbọ́ ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ìwọ ọmọ inú mi!Gbọ́ ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ́ mi.

3Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin,okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run.

4“Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli,kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì,kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle,

5kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí,kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n.

6Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbéwáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora.

7Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọnkí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.

8“Sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fúnra wọnfún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun.

9Sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbèjà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.”

Ìkádìí: Aya oníwà rere

10Ta ni ó le rí aya oníwà rere?Ó níye lórí ju iyùn lọ.

11Ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ nínú rẹ̀kò sì ṣí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.

12Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibiní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

13Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.

14Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò;ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn.

15Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn;ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.

16Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á;nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀.

17Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbáraapá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́.

18Ó rí i pé òwò òun péfìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru.

19Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú múó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú.

20O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákàó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.

21Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.

22Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀;ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀.

23A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlúníbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú.

24Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́nó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò.

25Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.

26A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́nìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀

27Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.

28Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkúnọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un.

29“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́láṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ.”

30Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asánnítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn.

31Sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí ikí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibodè ìlú.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]