Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 19 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 Better is a poor person who walks in his integrity than one whose words are crooked and is a fool. Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà.
2 Also, desire without knowledge is not good, and whoever acts in haste misses the way. Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀, tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà.
3 A person's own foolishness ruins his way, yet his heart rages against our Father. Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run; síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí Olúwa.
4 Wealth adds many friends, but the poor is separated from his friend. Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
5 A false witness will not go unpunished, and one who breathes out lies will not escape. Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.
6 Many seek the favor of a generous person, and everyone is a friend to one who gives gifts. Ọ̀pọ̀ ń wá ojúrere olórí; gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́.
7 All the brothers of a poor person hate him; how much more do his friends keep far from him! He calls after them, but they are gone. Gbogbo ará ilé e tálákà ni ó pa á tì, mélòó mélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un! Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀, kò tilẹ̀ le rí wọn rárá.
8 Whoever gets wisdom loves his own soul; whoever guards understanding will find good. Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀; ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.
9 A false witness will not go unpunished, and one who breathes out lies will perish. Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.
10 Luxury is not fitting for a fool—much less for a servant to rule over princes. Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọláńlá, mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jẹ ọba lórí ọmọ-aládé.
11 The good sense of a person makes him slow to anger, and it is his glory to overlook an offense. Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù; fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.
12 A king's wrath is like the roaring of a lion, but his favor is like dew on the grass. Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún, ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.
13 A foolish son is ruin to his father, and a wife's quarreling is a continual dripping. Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀, aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò.
14 House and wealth are an inheritance from one's ancestors, but a prudent wife is from our Father. A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí, ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni.
15 Laziness casts into deep sleep, and an idle person will go hungry. Ọ̀lẹ ṣíṣe máa ń fa oorun sísùn fọnfọn, ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.
16 Whoever keeps the commandment keeps his life; whoever despises his ways will die. Ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.
17 Whoever is generous to the poor lends to our Father, and our Father will repay him for his deed. Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, Olúwa ní ó yá, yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.
18 Discipline your son while there is hope, and do not set your heart on his destruction. Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà; àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú ìparun un rẹ̀.
19 A person of great wrath must pay the penalty; for if you rescue him, you will only have to do it again. Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀; bí ìwọ bá gbà á là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i.
20 Listen to counsel and accept discipline, that you may gain wisdom in the days to come. Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́, ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.
21 Many are the plans in a person's heart, but it is the counsel of our Father that will stand. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn, ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.
22 What is desired in a person is covenant love, and a poor person is better than a liar. Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀; ó sàn láti jẹ́ tálákà ju òpùrọ́ lọ.
23 The fear of our Father leads to life, and whoever has it rests satisfied, untouched by harm. Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá; nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láìsí ewu.
24 The sluggard buries his hand in the dish and will not even bring it back to his mouth. Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ; kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
25 Strike a mocker, and the simple will learn prudence; reprove a person of understanding, and he will gain knowledge. Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n; bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ sí i.
26 Whoever does violence to his father and drives away his mother is a son who brings shame and disgrace. Ẹni tí ó ṣìkà sí baba rẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde òun ni ọmọ tí ń ṣe ìtìjú, tí ó sì mú ẹ̀gàn wá.
27 Stop listening to instruction, my son, and you will stray from the words of knowledge. Ọmọ mi, dẹ́kun láti tẹ́tí sí ẹ̀kọ́, tí í mú ni ṣìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀-ìmọ̀.
28 A worthless witness mocks at justice, and the mouth of the wicked gulps down wickedness. Ẹlẹ́rìí búburú fi ìdájọ́ ṣẹ̀sín, ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mì.
29 Punishment is prepared for mockers, and beatings for the backs of fools. A ti pèsè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn; àti pàṣán fún ẹ̀yìn àwọn aṣiwèrè.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]