Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 20 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 Wine is a mocker, strong drink a brawler, and whoever staggers under it is not wise. Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọtí líle; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi tànjẹ kò gbọ́n.
2 The terror of a king is like the growl of a lion; whoever provokes him to anger forfeits his own life. Ìbẹ̀rù ọba dàbí kíké e kìnnìún; ẹnikẹ́ni tí ó bá mú un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́.
3 It is an honor for a person to keep clear of strife, but every fool is quick to quarrel. Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà, ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.
4 A lazy person will not plow in autumn; so at harvest he looks for a crop and finds nothing. Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ, nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.
5 The purposes of a person's heart are deep waters, but one who has understanding draws them out. Ète ọkàn ènìyàn dàbí omi jíjìn; ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.
6 Many a person proclaims his own loyal love, but a faithful one—who can find? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń sọ pe àwọn ní ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn, ṣùgbọ́n kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòtítọ́.
7 The righteous walk in their integrity; blessed are their children after them! Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkù ìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.
8 A king seated on the throne of judgment winnows out all evil with his eyes. Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀.
9 Who can say, "I have kept my heart pure; I am cleansed from my sin"? Ta ni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́, mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?
10 Unequal weights and unequal measures—our Father detests them both. Ìwọ̀n èké àti òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ Olúwa kórìíra méjèèjì.
11 Even a child is known by his actions, by whether his conduct is pure and upright. Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀ nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà.
12 The hearing ear and the seeing eye—our Father made them both. Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran Olúwa ni ó dá méjèèjì.
13 Do not love sleep, or you will grow poor; open your eyes, and you will have plenty of bread. Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di tálákà. Ma ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ.
14 "Worthless, worthless!" says the buyer—then off he goes and boasts of his bargain. “Kò dára, kò dára!” ní ẹni tó ra ọjà máa ń wí; nígbà tí ó bá kúrò níbẹ̀ tán, yóò máa yangàn bí òun tí ṣe rí rà sí.
15 There is gold and an abundance of jewels, but lips that speak knowledge are a rare treasure. Wúrà wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹ, ṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye.
16 Take the garment of one who puts up security for a stranger; hold it as a pledge when he does so for foreigners. Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò; mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn.
17 Bread gained by deceit tastes sweet, but afterward the mouth is full of gravel. Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn, ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀.
18 Plans are established by counsel; so wage war only with wise guidance. Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀ràn bí o bá ń jagun, gba ìtọ́sọ́nà.
19 A gossip betrays a confidence; so do not keep company with a babbler. Olófòófó a máa tú àṣírí nítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ púpọ̀.
20 Whoever curses his father or mother—his lamp will be snuffed out in deepest darkness. Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri.
21 An inheritance gained too quickly at the start will not be blessed in the end. Ogún tí a kójọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín.
22 Do not say, "I will pay back evil for evil." Wait for our Father, and he will deliver you. Má ṣe wí pé, “N ó sẹ̀san àṣìṣe rẹ yìí fún ọ.” Dúró de Olúwa yóò sì gbà ọ́ là.
23 Our Father detests unequal weights, and dishonest scales are no good. Olúwa kórìíra òdínwọ̀n èké. Òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.
24 A person's steps are directed by our Father; how then can anyone understand his own way? Olúwa ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyàn. Báwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni?
25 It is a trap to rashly dedicate something and only later reconsider the vow. Ìdẹ̀kùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíá nígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.
26 A wise king winnows out the wicked and drives the threshing wheel over them. Ọlọ́gbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká; Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n.
27 The human spirit is the lamp of our Father, searching every inmost part. Àtùpà Olúwa ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàn a máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú.
28 Loyal love and faithfulness preserve a king; by loyal love his throne is upheld. Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́, nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu.
29 The glory of the young is their strength, but the splendor of the old is gray hair. Ògo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn, ewú orí ni iyì arúgbó.
30 Wounding blows scrub away evil, and beatings cleanse the inmost parts. Ìgbájú ìgbámú àti ìfarapa máa ń mú ibi lọ, pàṣán sì máa ń ṣe àfọ̀mọ́ ibi ìkọ̀kọ̀ inú.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]