Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 19 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

1Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkùju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà.

2Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀,tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà.

3Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run;síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí Olúwa.

4Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀;ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

5Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.

6Ọ̀pọ̀ ń wá ojúrere olórí;gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́.

7Gbogbo ará ilé e tálákà ni ó pa á tì,mélòó mélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un!Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀,kò tilẹ̀ le rí wọn rárá.

8Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀;ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.

9Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyàẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.

10Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọláńlá,mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jẹ ọba lórí ọmọ-aládé.

11Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù;fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.

12Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún,ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.

13Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀,aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò.

14A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí,ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni.

15Ọ̀lẹ ṣíṣe máa ń fa oorun sísùn fọnfọn,ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.

16Ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́,ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.

17Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, Olúwa ní ó yá,yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.

18Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà;àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú ìparun un rẹ̀.

19Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀;bí ìwọ bá gbà á là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i.

20Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́,ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.

21Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn,ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.

22Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀;ó sàn láti jẹ́ tálákà ju òpùrọ́ lọ.

23Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá;nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láìsí ewu.

24Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ;kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.

25Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n;bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ sí i.

26Ẹni tí ó ṣìkà sí baba rẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jádeòun ni ọmọ tí ń ṣe ìtìjú, tí ó sì mú ẹ̀gàn wá.

27Ọmọ mi, dẹ́kun láti tẹ́tí sí ẹ̀kọ́,tí í mú ni ṣìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀-ìmọ̀.

28Ẹlẹ́rìí búburú fi ìdájọ́ ṣẹ̀sín,ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mì.

29A ti pèsè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn;àti pàṣán fún ẹ̀yìn àwọn aṣiwèrè.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]