Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 17 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 Better a dry crust eaten in peace than a house full of feasting with strife. Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sàn ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.
2 A prudent servant will rule over a disgraceful son and will share the inheritance among the brothers. Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ, yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ.
3 The crucible is for silver and the furnace for gold, but our Father tests hearts. Iná ni a fi fọ́ fàdákà àti wúrà, ṣùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò.
4 An evildoer listens to wicked lips; a liar listens to a destructive tongue. Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi; òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú.
5 Whoever mocks the poor insults his Maker; whoever gloats over disaster will not go unpunished. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sín olùpọ́njú jẹ, ó gan Ẹlẹ́dàá rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ sí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà.
6 Grandchildren are the crown of the aged, and the glory of children is their parents. Ọmọ ọmọ ni adé orí arúgbó, ògo àwọn ọmọ sì ni òbí jẹ.
7 Fine speech is not fitting for a fool—still less are lying lips for a noble. Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aṣiwèrè, bẹ́ẹ̀ ni ètè èké kò yẹ ọmọ-aládé!
8 A bribe seems like a magic charm to the one who gives it; wherever he turns, he thinks he will succeed. Òkúta iyebíye jẹ́ ẹ̀bùn ní ojú ẹni tí ó ni í, ibikíbi tí ó yí sí, á ṣe rere.
9 Whoever covers an offense seeks love, but whoever keeps bringing it up separates close friends. Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì ní yà.
10 A rebuke goes deeper into a person of understanding than one hundred blows into a fool. Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun olóye ènìyàn ju ọgọ́rùn-ún pàṣán lọ lẹ́yìn òmùgọ̀.
11 A rebellious man seeks only evil, and a cruel messenger will be sent against him. Orí kunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe, ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i.
12 Better to meet a bear robbed of her cubs than a fool in his foolishness. Ó sàn kí ènìyàn pàdé beari tí a ti kó lọ́mọ jù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
13 If anyone returns evil for good, evil will never leave his house. Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ìre, ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé.
14 Starting a quarrel is like breaching a dam, so drop the dispute before it bursts out. Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi; nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.
15 Whoever justifies the wicked and whoever condemns the righteous—both alike are detestable to our Father. Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi, Olúwa kórìíra méjèèjì.
16 Why should a fool have money in hand to buy wisdom, when he has no heart to learn? Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrè, níwọ̀n bí kò ti ní èròǹgbà láti rí ọgbọ́n?
17 A friend loves at all times, and a brother is born for a time of trouble. Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.
18 One who lacks sense shakes hands on a pledge and puts up security for his neighbor. Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúra, ó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.
19 Whoever loves wrongdoing loves strife; whoever builds his gate high invites destruction. Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀; ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun.
20 A crooked heart finds no good, and a twisted tongue falls into trouble. Ènìyàn aláyídáyidà ọkàn kì í gbèrú, ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu.
21 Whoever fathers a fool brings grief on himself; the father of a godless fool has no joy. Láti bí aláìgbọ́n lọ́mọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn, kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n.
22 A joyful heart is good medicine, but a crushed spirit dries up the bones. Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi, ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.
23 A wicked man takes a bribe in secret to pervert the ways of justice. Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ láti yí ìdájọ́ po.
24 A discerning person keeps wisdom in view, but the eyes of a fool wander to the ends of the earth. Olóye ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájú, ṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé.
25 A foolish son is a grief to his father and bitterness to the mother who bore him. Aṣiwèrè ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀ àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ.
26 To punish the righteous is not good, nor to flog the noble for their integrity. Kò dára láti fìyà jẹ ènìyàn tí kò ṣẹ̀, tàbí láti na ìjòyè lórí òtítọ́ inú wọn.
27 Whoever holds back his words has knowledge, and one with a calm spirit is a person of understanding. Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, ènìyàn olóye sì máa ń ní sùúrù.
28 Even a fool who keeps silent is thought wise; when he closes his lips, he seems discerning. Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọ́gbọ́n bí ó bá dákẹ́, àti bí olóye bí ó bá fètèmétè.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]