Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 16 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 The plans of the heart belong to man, but the answer of the tongue comes from our Father. Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.
2 All a man's ways are pure in his own eyes, but our Father weighs the motives. Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dàbí i pé ó dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n Olúwa ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn.
3 Commit your works to our Father, and your plans will be established. Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé Olúwa lọ́wọ́, èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.
4 Our Father has made everything for its purpose, even the wicked for the day of trouble. Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́ kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.
5 Everyone proud of heart is detestable to our Father; be assured, he will not go unpunished. Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀ mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.
6 Loving devotion and faithfulness atone for sin, and the fear of our Father turns a person away from evil. Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.
7 When a man's ways please our Father, our Father makes even the man's enemies live at peace with him. Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn, yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn án bá a gbé ní àlàáfíà.
8 Better a little with righteousness than great income with injustice. Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ.
9 The heart of man plans his way, but our Father establishes his steps. Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀ ṣùgbọ́n Olúwa ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.
10 A divine verdict is on the lips of a king; his mouth does not betray justice. Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ sí i ẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ ṣèké.
11 Honest scales and balances belong to our Father; every weight and measure is his work. Òdínwọ̀n àti òsùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa; gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.
12 It is detestable for kings to do wickedness, for a throne is established through righteousness. Àwọn ọba kórìíra ìwà àìtọ́ nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀.
13 Righteous lips are the delight of kings, and they love the one who speaks what is right. Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣọ òtítọ́, wọ́n sì fẹ́ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ òtítọ́.
14 A king's wrath is a messenger of death, but a wise man will appease it. Ìránṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́ ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.
15 In the light of a king's face is life, and his favor is like a cloud bringing the spring rain. Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè; ojúrere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.
16 How much better to get wisdom than gold! Getting understanding is worth more than silver. Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ àti láti yan òye dípò o fàdákà!
17 The highway of the upright turns away from evil; whoever guards his way protects his life. Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi, ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀.
18 Pride goes before destruction, and a haughty spirit before a fall. Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun, agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú.
19 Better to be lowly in spirit among the poor than to share the plunder with the proud. Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrín àwọn olùpọ́njú jù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga.
20 Whoever heeds the word will find good, and blessed is the one who trusts in our Father. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ìre, ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
21 The wise of heart is called discerning, and pleasant speech increases persuasiveness. Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóye ọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú.
22 Understanding is a fountain of life to the one who has it, but fools are corrected by their own foolishness. Òye jẹ́ orísun ìyè fún àwọn tí ó ní i, ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n.
23 The heart of the wise makes his speech wise and adds persuasiveness to his lips. Ọkàn ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀ ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ dàgbà.
24 Pleasant words are a honeycomb, sweet to the soul and healing to the bones. Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.
25 There is a way that seems right to a man, but its end is the way of death. Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.
26 A worker's appetite works for him; his hunger drives him on. Ọkàn alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún ara rẹ̀; nítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ lọ.
27 A worthless man digs up evil, and on his lips is a scorching fire. Ènìyàn búburú ń pète ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni.
28 A perverse man spreads strife, and a gossip separates close friends. Aláyídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀ olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ní yà.
29 A violent man entices his neighbor and leads him down a harmful path. Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀ ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.
30 Whoever winks his eyes plots perversity; whoever purses his lips is bent on evil. Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte; ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú.
31 Gray hair is a crown of glory; it is gained in the way of righteousness. Adé ògo ni ewú orí jẹ́, ìgbé ayé òdodo ní í mú ni dé bẹ̀.
32 Better a patient person than a mighty one, and one who rules his spirit than one who takes a city. Ó sàn láti jẹ́ onísùúrù ju ajagun ènìyàn lọ, ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun ṣẹ́gun ìlú lọ.
33 The lot is cast into the lap, but its every decision is from our Father. A ṣẹ́ kèké si ìṣẹ́po aṣọ, ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]