Side by side with the Father's Heart Bible™ 1Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sànju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.
2Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ,yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ.
3Iná ni a fi fọ́ fàdákà àti wúrà,ṣùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò.
4Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi;òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú.
5Ẹnikẹ́ni tí ó bá sín olùpọ́njú jẹ, ó gan Ẹlẹ́dàá rẹ̀,ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ sí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà.
6Ọmọ ọmọ ni adé orí arúgbó,ògo àwọn ọmọ sì ni òbí jẹ.
7Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aṣiwèrè,bẹ́ẹ̀ ni ètè èké kò yẹ ọmọ-aládé!
8Òkúta iyebíye jẹ́ ẹ̀bùn ní ojú ẹni tí ó ni í,ibikíbi tí ó yí sí, á ṣe rere.
9Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i.Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì ní yà.
10Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun olóye ènìyànju ọgọ́rùn-ún pàṣán lọ lẹ́yìn òmùgọ̀.
11Orí kunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe,ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i.
12Ó sàn kí ènìyàn pàdé beari tí a ti kó lọ́mọjù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
13Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ìre,ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé.
14Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi;nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.
15Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi,Olúwa kórìíra méjèèjì.
16Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrè,níwọ̀n bí kò ti ní èròǹgbà láti rí ọgbọ́n?
17Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.
18Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúra,ó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.
19Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀;ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun.
20Ènìyàn aláyídáyidà ọkàn kì í gbèrú,ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu.
21Láti bí aláìgbọ́n lọ́mọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn,kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n.
22Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi,ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.
23Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀láti yí ìdájọ́ po.
24Olóye ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájú,ṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé.
25Aṣiwèrè ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ.
26Kò dára láti fìyà jẹ ènìyàn tí kò ṣẹ̀,tàbí láti na ìjòyè lórí òtítọ́ inú wọn.
27Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ,ènìyàn olóye sì máa ń ní sùúrù.
28Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọ́gbọ́n bí ó bá dákẹ́,àti bí olóye bí ó bá fètèmétè.