Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Job 35 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Olóòtítọ́ ni Ọlọ́run

1Elihu sì wí pe:

2“Ìwọ rò pé èyí ha tọ́, tí ìwọ wí pé,òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọ́run?

3Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóò jásí fún ọ,tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.

4“Èmi ó dá ọ lóhùnàti àwọn ẹgbẹ́ rẹ pẹ̀lú rẹ.

5Síjú wo ọ̀run; kí o rí i, kí ó sìbojú wo àwọsánmọ̀ tí ó ga jù ọ́ lọ.

6Bí ìwọ bá dẹ́ṣẹ̀, kí ni ìwọ fi sẹ̀ sí?Tàbí bí ìrékọjá rẹ di púpọ̀, kí ni ìwọ fi èyí nì ṣe sí i?

7Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọ fi fún un,tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?

8Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bí ìwọ;òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn.

9“Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n mú ni kígbe;wọ́n kígbe nípa apá àwọn alágbára.

10Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé,‘Níbo ni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru;

11tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọn ẹranko ayé lọ,tí ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’

12Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dáhùnnítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.

13Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ asán;bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí.

14Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì í rí i,ọ̀rọ̀ ìdájọ́ ń bẹ níwájú rẹ,ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè.

15Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nítorí tí ìbínú rẹ̀ kò tí fìyà jẹ ni,òun kò ni ka ìwà búburú si?

16Nítorí náà ní Jobu ṣe ya ẹnu rẹ̀lásán ó sọ ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìsí ìmọ̀.”

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]