Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Lamentations 5 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 Remember, our Father, what has happened to us; look and see our disgrace. Rántí, Olúwa, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa; wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.
2 Our inheritance has been turned over to strangers, our homes to foreigners. Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò, ilé wa ti di ti àjèjì.
3 We have become orphans, fatherless; our mothers are like widows. Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba, àwọn ìyá wa ti di opó.
4 We pay for our own water to drink; even firewood costs us money. A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu; igi wa di títà fún wa.
5 Our pursuers are at our necks; we are worn out and given no rest. Àwọn tí ó ń lé wa súnmọ́ wa; àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.
6 We submitted to Egypt and Assyria just to get enough bread. Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Ejibiti àti Asiria láti rí oúnjẹ tó tó jẹ.
7 Our ancestors sinned, and are no more; and we bear their punishment. Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣí mọ́, àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
8 Slaves rule over us; there is no one to free us from their grip. Àwọn ẹrú ń jẹ ọba lórí wa, kò sì ṣí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.
9 We risk our lives to get our bread, because of the sword in the wilderness. Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wa nítorí idà tí ó wà ní aginjù.
10 Our skin is hot as an oven, scorched by the burning heat of famine. Ẹran-ara wa gbóná bí ààrò, ebi sì yó wa bí àárẹ̀.
11 Women are violated in Zion, virgins in the cities of Judah. Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lòpọ̀ ní Sioni, àti àwọn wúńdíá ti o wa ní ìlú Juda.
12 Princes are hung up by their hands; the elders receive no respect. Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di síso sókè ní ọwọ́ wọn; kò sí ìbọ̀wọ̀ fún àgbàgbà mọ́.
13 Young men toil at the millstones; boys stagger under loads of wood. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa ru òkúta; àwọn ọmọkùnrin sì ń ṣàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.
14 The elders have left the city gate, the young men their music. Àwọn àgbàgbà ti lọ kúrò ní ẹnu-bodè ìlú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn.
15 The joy of our hearts has ceased; our dancing has turned to mourning. Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa; ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.
16 The crown has fallen from our head. Woe to us, for we have sinned! Adé ti ṣí kúrò ní orí wa ègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.
17 Because of this our heart has grown faint; because of these things our eyes have grown dim. Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa, nítorí èyí, ojú wa sì ṣú.
18 For Mount Zion lies desolate; jackals prowl over it. Fún òkè Sioni tí ó ti di ahoro lórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.
19 You, our Father, are enthroned forever; your throne endures from generation to generation. Ìwọ, Olúwa, jẹ ọba títí láé; ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.
20 Why do you forget us forever, forsake us for so many days? Kí ló dé tí o ń gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà? Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́?
21 Restore us to yourself, our Father, and we will return; renew our days as they once were, Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, Olúwa, kí àwa kí ó le padà; mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbàanì,
22 unless you have utterly rejected us, and are angry with us beyond measure. àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá tí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]