Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Proverbs 30 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 The words of Agur son of Jakeh—the oracle. The man declares: I am weary, O my Father; I am weary, O my Father, and worn out. Àwọn ọ̀rọ̀ Aguri ọmọ Jake, ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí ọkùnrin yìí sọ fún Itieli. Sí Itieli àti sí Ukali.
2 Surely I am too brutish to be a man; I do not have the understanding of a man. “Èmi ni aláìmòye ju nínú àwọn ènìyàn; n kò ní òye ènìyàn.
3 I have not learned wisdom, nor do I have knowledge of the Holy One. Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́n tàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì.
4 Who has ascended to heaven and come down? Who has gathered the wind in the hollow of his hands? Who has wrapped the waters in a garment? Who has established all the ends of the earth? What is his name, and what is his son's name? Surely you know! Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀? Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀? Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ? Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀? Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀? Sọ fún mi bí o bá mọ̀.
5 Every word of our Father proves true; he is a shield to those who take refuge in him. “Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù; òun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn.
6 Do not add to his words, or he will rebuke you and prove you a liar. Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́.
7 Two things I ask of you; do not withhold them from me before I die: “Ohun méjì ni mo ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa; má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú.
8 Keep falsehood and lies far from me; give me neither poverty nor riches; feed me only the bread that is my portion, Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi; má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀, ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan.
9 for if I am full, I may deny you and say, "Who is God?" or if I am poor, I may steal and profane the name of my God. Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹ kí ń sì wí pé, ‘Ta ni Olúwa?’ Tàbí kí ń di òtòṣì kí ń sì jalè kí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi.
10 Do not slander a servant to his master, or he will curse you and you will be found guilty. “Má ṣe ba ìránṣẹ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, kí ó má ba fi ọ́ bú, kí ìwọ má ba jẹ̀bi.
11 There is a generation that curses its father and does not bless its mother. “Àwọn kan wá ṣépè fún àwọn baba wọn tí wọn kò sì súre fún àwọn ìyá wọn.
12 There is a generation clean in its own eyes yet not washed of its filth. Àwọn tí ó mọ́ ní ojú ara wọn síbẹ̀ tí wọn kò sì mọ́ kúrò nínú èérí wọn;
13 There is a generation—how proud its eyes, how scornful its glances! àwọn ẹni tí ojú wọn gbéga nígbà gbogbo, tí ìwolẹ̀ wọn sì kún fún ìgbéraga.
14 There is a generation whose teeth are swords, whose fangs are knives, to devour the poor from the earth and the needy from among mankind. Àwọn ẹni tí eyín wọn jẹ́ idà àwọn tí èrìgì wọn kún fún ọ̀bẹ láti jẹ àwọn tálákà run kúrò ní ilẹ̀ ayé àwọn aláìní kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
15 The leech has two daughters: "Give" and "Give." Three things are never satisfied; four never say, "Enough": “Eṣúṣú ni ọmọbìnrin méjì. ‘Mú wá! Mú wá!’ ní wọn ń ké. “Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn láéláé, mẹ́rin tí kò jẹ́ wí láéláé pé, ‘Ó tó!’:
16 The grave, the barren womb, the land never satisfied with water, and the fire that never says, "Enough." Ibojì, inú tí ó yàgàn, ilẹ̀ tí omi kì í tẹ́lọ́rùn láéláé, àti iná, tí kì í wí láéláé pé, ‘Ó tó!’
17 The eye that mocks a father and scorns to obey a mother—the ravens of the valley will pluck it out, and the young vultures will eat it. “Ojú tí ń fi baba ṣẹ̀fẹ̀, tí ó kẹ́gàn ìgbọ́ràn sí ìyá, ẹyẹ ìwò ẹ̀bá odò ni yóò yọ ọ́, igún yóò mú un jẹ.
18 Three things are too wonderful for me; four I do not understand: “Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi, mẹ́rin tí kò yé mi,
19 the way of an eagle in the sky, the way of a serpent on a rock, the way of a ship in the heart of the sea, and the way of a man with a young woman. ipa ẹyẹ idì ní òfúrufú ipa ejò lórí àpáta ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami Òkun àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúńdíá lọ́wọ́.
20 This is the way of an adulteress: she eats and wipes her mouth and says, "I have done no wrong." “Èyí ni ọ̀nà alágbèrè obìnrin ó jẹun ó sì nu ẹnu rẹ̀ ó sì wí pé, ‘N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́.’
21 Under three things the earth trembles; under four it cannot bear up: “Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ilé ayé ti ń wárìrì lábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín.
22 a servant when he becomes king, and a fool when he is filled with food; Ìránṣẹ́ tí ó di ọba aláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,
23 an unloved woman when she finally marries, and a servant girl when she displaces her mistress. obìnrin tí gbogbo ènìyàn kórìíra tí ó sì wá lọ́kọ ìránṣẹ́bìnrin tí ó gbọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.
24 Four things on earth are small, yet they are exceedingly wise: “Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyé síbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi.
25 the ants are a people not strong, yet they store up their food in the summer; Àwọn èèrà jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá, síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò.
26 the rock badgers are a people not mighty, yet they make their homes in the cliffs; Ehoro jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá; síbẹ̀ wọ́n ń ṣe ihò wọn sí ibi pálapàla àpáta;
27 the locusts have no king, yet all of them advance in ranks; àwọn eṣú kò ní ọba, síbẹ̀ gbogbo wọ́n ń jáde lọ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́
28 the lizard you can catch in your hands, yet it is found in kings' palaces. Ọmọnílé fi ọwọ́ rẹ̀ dì mú, síbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.
29 Three things are stately in their stride; four are stately in their walk: “Àwọn ohun mẹ́ta ní ń bẹ tí ń rìn rere, ohun mẹ́rin ni ó dára púpọ̀ ní ìrìn rírìn:
30 the lion, mightiest among beasts, which turns back before nothing; Kìnnìún, alágbára láàrín ẹranko tí kì í sá fún ohunkóhun
31 the strutting rooster, the male goat, and a king whose army is with him. Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́; àti òbúkọ, àti ọba láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
32 If you have been foolish, exalting yourself, or if you have schemed evil, put your hand over your mouth. “Bí ìwọ bá ti hùwà aṣiwèrè nípa gbígbé ara rẹ ga, tàbí tí o bá ti gbèrò ibi, da ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ!
33 For pressing milk produces curds, pressing the nose produces blood, and pressing anger produces strife. Nítorí bí fífún omi ọmú tí í mú wàrà wá, tí fífún imú sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde, bẹ́ẹ̀ ni rírú ìbínú sókè í mú ìjà wá.”
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]