1Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburúmá ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;
2nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ohun búburú,ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀.
3Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́nípa òye sì ni ó ti fìdímúlẹ̀;
4nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kúnpẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.
5Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀,ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára sí i.
6Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà:nínú ìṣẹ́gun ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.
7Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrèàti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí.
8Ẹni tí ń pète ibini a ó mọ̀ bí ènìyàn ibi.
9Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn.
10Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmúbáwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó!
11Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là;fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà.
12Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,”ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsi i? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́n?Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?
13Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára,oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.
14Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹbí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọìrètí rẹ kì yóò sì já ṣófo.
15Má ṣe ba ní ibùba bí ènìyàn búburúláti gba ibùjókòó olódodo,má ṣe fi ibi ìsinmi rẹ̀ ṣe ìjẹ;
16nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbà méje, yóò tún padà dìde sá á ni,ṣùgbọ́n ìdààmú yóò fa ènìyàn búburú lulẹ̀.
17Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú;nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀.
18Àìṣe bẹ́ẹ̀ Olúwa yóò rí i yóò sì bínúyóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
19Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibitàbí jowú àwọn ènìyàn búburú,
20nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájúa ó sì pa fìtílà àwọn ènìyàn búburú kú.
21Bẹ̀rù Olúwa àti ọba, ọmọ mi,má sì ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun.
22Nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn,ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá?
Àwọn ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n mìíràn
23Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n:láti ṣe ojúsàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá.
24Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre,”àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kọ̀ ọ́.
25Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi,ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.
26Ìdáhùn òtítọ́dàbí ìfẹnukoni ní ẹnu.
27Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹsì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára;lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.
28Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládùúgbò rẹ láìnídìí,tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.
29Má ṣe wí pé, “Èmi yóò ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi;Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”
30Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ,mo kọjá níbi ọgbà àjàrà aláìgbọ́n ènìyàn;
31ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo,koríko ti gba gbogbo oko náà.
32Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsimo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí;
33oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi,
34òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalèàti àìní bí olè.