Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Lamentations 2 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

1Báwo ni Olúwa ṣe bo ọmọbìnrin Sionipẹ̀lú àwọsánmọ̀ ìbínú rẹ̀!Ó sọ ògo Israẹli kalẹ̀,láti ọ̀run sí ayé;kò rántí àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀.

2Láìní àánú ni Olúwa gbéibùgbé Jakọbu mì;nínú ìrunú rẹ̀, ni ó wóibi gíga ọmọbìnrin Juda lulẹ̀.Ó ti mú ìjọba àti àwọn ọmọ-aládé ọkùnrinlọ sínú ilẹ̀ ní àìlọ́wọ̀.

3Ní ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó kégbogbo ìwo Israẹli.Ó ti mú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrònígbà tí àwọn ọ̀tá dé.Ó run ní Jakọbu bí ọ̀wọ́-inání àgọ́ àwọn ọmọbìnrin Sioni.

4Ó na ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá;ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sì múra.Bí ti ọ̀tá tí ó ti parunó tú ìbínú rẹ̀ jáde bí inásórí àgọ́ ọmọbìnrin Sioni.

5Olúwa dàbí ọ̀tá;ó gbé Israẹli mì.Ó ti gbé gbogbo ààfin rẹ̀ mìó pa ibi gíga rẹ̀ run.Ó sọ ìmí ẹ̀dùn àti ìbànújẹ́ di púpọ̀fún àwọn ọmọbìnrin Juda.

6Ó mú ìparun bá ibi mímọ́,ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run.Olúwa ti mú Sioni gbàgbéàjọ̀dún tí a yàn àti ọ̀sẹ̀ tí ó yàn;nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó runọba àti olórí àlùfáà.

7Olúwa ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀.Ó sì fi lé ọ̀tá lọ́wọ́àwọn odi ààfin rẹ̀;wọ́n sì kígbe ní ilé Olúwagẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àpèjẹ tí a yàn.

8Olúwa pinnu láti faògiri tí ó yí ọmọbìnrin Sioni ya.Ó gbé wọn sórí òsùwọ̀n,kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn.Ó mú kí ilé ìṣọ́ àti odi rẹ̀ ṣọ̀fọ̀wọ́n ṣòfò papọ̀.

9Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀;òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́.Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,kò sí òfin mọ́,àwọn wòlíì rẹ̀ kò ríìran láti ọ̀dọ̀ Olúwa mọ́.

10Àwọn àgbàgbà ọmọbìnrin Sionijókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́;wọ́n da eruku sí orí wọnwọ́n sì wọ aṣọ àkísà.Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jerusalẹmuti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀.

11Ojú mi kọ̀ láti sọkún,mo ń jẹ ìrora nínú mi,mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run,nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kúní òpópó ìlú.

12Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn,“Níbo ni ọkà àti wáìnì wà?” Wò óbí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣení àwọn òpópónà ìlú,bí ayé wọn ṣe ń ṣòfòláti ọwọ́ ìyá wọn.

13Kí ni mo le sọ fún ọ?Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé,ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu?Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé,kí n lè tù ọ́ nínú,ìwọ wúńdíá obìnrin Sioni?Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun.Ta ni yóò wò ọ́ sàn?

14Ìran àwọn wòlíì rẹjẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n;wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàntí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ.Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọjẹ́ èké àti ìmúniṣìnà.

15Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹpàtẹ́wọ́ lé ọ lórí;wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọnsí ọmọbìnrin Jerusalẹmu:“Èyí ha ni ìlú tí à ń pèní àṣepé ẹwà,ìdùnnú gbogbo ayé?”

16Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọngbòòrò sí ọ;wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payínkekewọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán.Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí;tí a sì wá láti rí.”

17Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu;ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́.Ó ti ṣí ọ ní ipò láì láàánú,ó fún ọ̀tá ní ìṣẹ́gun lórí rẹ,ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga.

18Ọkàn àwọn ènìyànkígbe jáde sí Olúwa.Odi ọmọbìnrin Sioni,jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ sàn bí odòní ọ̀sán àti òru;má ṣe fi ara rẹ fún ìtura,ojú rẹ fún ìsinmi.

19Dìde, kígbe sókè ní àṣálẹ́,bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀tú ọkàn rẹ̀ jáde bí ominíwájú Olúwa.Gbé ọwọ́ yín sókè sí inítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀tí ó ń kú lọ nítorí ebiní gbogbo oríta òpópó.

20“Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó.Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí.Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn,àwọn ọmọ tí wọn ń ṣe ìtọ́jú fún?Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíìní ibi mímọ́ Olúwa?

21“Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀sínú eruku àwọn òpópó;àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin miti ṣègbé nípa idà.Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ,Ìwọ pa wọ́n láìní àánú.

22“Bí ó ti ṣe ní ọjọ́ àsè,bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi ẹ̀rù sí ẹ̀gbẹ́ mi.Ní ọjọ́ ìbínú Olúwakò sí ẹni tí ó sálà tí ó sì yè;àwọn tí mo ti tọ́jú tí mo sì fẹ́ràn,ni ọ̀tá mi parun.”

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]