Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Job 40 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

Jobu rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀

1Olúwa dá Jobu lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wí pé,

2“Ẹni tí ń bá Olódùmarè wíjọ́ yóò ha kọ ní ẹ̀kọ́?Ẹni tí ń bá Ọlọ́run wí jẹ́ kí ó dáhùn!”

3Nígbà náà ni Jobu dá Olúwa lóhùn wá ó sì wí pé,

4“Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà?Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi.

5Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò tún sọ mọ́;lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì le ṣe é mọ́.”

6Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé,

7“Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin,èmi ó bi ọ léèrè,kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.

8“Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán?Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo.

9Ìwọ ni apá bí Ọlọ́runtàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?

10Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́,tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ.

11Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde;kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.

12Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.

13Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀,kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú.

14Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé,ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.

15“Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti,tí mo dá pẹ̀lú rẹ,òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.

16Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.

17Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari,iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀.

18Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ,Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.

19Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run;síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.

20Nítòótọ́ òkè ńlá ńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá,níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀.

21Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì,lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀.

22Igi lótusì síji wọn bò o;igi arọrọ odò yí i káàkiri.

23Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ;ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.

24Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀,tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]