Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Isaiah 64 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

1Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!

2Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jótí ó sì mú kí omi ó hó,sọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mí mọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹkí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!

3Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí,o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ̀.

4Láti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ ríkò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.

5Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọnń fi ayọ̀ ṣe ohun tó tọ́,tí ó rántí ọ̀nà rẹ.Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn,inú bí ọ.Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?

6Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́,gbogbo òdodo wa sì dàbí èkísà ẹlẹ́gbin;gbogbo wa kákò bí ewé,àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.

7Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹtàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú;nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún waó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.

8Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa, ìwọ ni Baba wa.Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò;gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

9Má ṣe bínú kọjá ààlà, ìwọ Olúwa,má ṣe rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé.Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà,nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.

10Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀;Sioni pàápàá di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu di ahoro.

11Tẹmpili mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́,ni a ti fi iná sun,àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro.

12Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, Olúwa, ìwọ ó ha sì tún fi ara rẹ pamọ́ bí?Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹ wá kọjá ààlà bí?

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]