Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Isaiah 52 OYCB

Side by side with the Father's Heart Bible™

1Jí, jí, ìwọ Sioni,wọ ara rẹ ní agbára.Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀,ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ n nì.Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́kì yóò wọ inú rẹ mọ́.

2Gbọn eruku rẹ kúrò;dìde sókè, kí o sì gúnwà, ìwọ Jerusalẹmu.Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò,ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbèkùn Sioni.

3Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí,“Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́,láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”

4Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí.“Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi sọ̀kalẹ̀lọ sí Ejibiti láti gbé;láìpẹ́ ni Asiria pọ́n wọn lójú.

5“Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni Olúwa wí.“Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́,àwọn tí ó sì ń jẹ ọba lórí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,”ni Olúwa wí.“Àti ní ọjọọjọ́orúkọ mi ni asọ̀rọ̀-òdì sí nígbà gbogbo.

6Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi;nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀pé, Èmi ni ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”

7Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkèẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìnrere ayọ̀ wá,tí wọ́n kéde àlàáfíà,tí ó mú ìyìnrere wá,tí ó kéde ìgbàlà,tí ó sọ fún Sioni pé,“Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!”

8Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókèwọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀.Nígbà tí Olúwa padà sí Sioni,wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn.

9Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀,ẹ̀yin ahoro Jerusalẹmu,nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú,ó sì ti ra Jerusalẹmu padà.

10Olúwa yóò ṣí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ní ojú gbogbo orílẹ̀-èdè,àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò ríìgbàlà Ọlọ́run wa.

11Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìn-ín yìí!Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan!Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò Olúwa.

12Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúròtàbí kí ẹ sáré lọ;nítorí Olúwa ni yóò síwájú yín lọ,Ọlọ́run Israẹli ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín.

Ìpọ́njú àti ògo ìránṣẹ́ náà

13Kíyèsi i, ìránṣẹ́ mi yóò hùwà ọlọ́gbọ́n;òun ni a ó gbé sókè tí a ó sì gbégaa ó sì gbé e lékè gidigidi.

14Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bu ọlá fún un—ìwò ojú rẹ ni a ti bàjẹ́ kọjá ti ẹnikẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́.

15Bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bomirin àwọn orílẹ̀-èdè ká,àwọn ọba yóò sì pa ẹnu wọn mọ́ nítorí rẹ̀.Nítorí ohun tí a kò sọ fún wọn, wọn yóò rí i,àti ohun tí wọn kò tí ì gbọ́, ni yóò sì yé wọn.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]