Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Hosea 7 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 Whenever I try to heal Israel, the sin of Ephraim is uncovered, and the evils of Samaria; for they practice falsehood—the thief breaks in, the raiders plunder outside. nígbà tí èmi ìbá mú Israẹli láradá. Ẹ̀ṣẹ̀ Efraimu ń farahàn ìwà búburú Samaria sì ń hàn síta. Wọ́n ń ṣe ẹ̀tàn, àwọn olè ń fọ́ ilé; àwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà;
2 But they do not say in their hearts that I remember all their evil. Now their deeds surround them; they are before my face. ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo rántí gbogbo ìwà búburú wọn. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátápátá; wọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo.
3 By their evil they make the king glad, and the princes by their lies. “Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn, àti inú ọmọ-aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn.
4 They are all adulterers, like an oven heated by the baker, who stops stirring the fire from the kneading of the dough until it is leavened. Alágbèrè ni gbogbo wọn wọ́n gbóná bí ààrò àkàrà tí a dáwọ́ kíkoná dúró, lẹ́yìn ìgbà tí o ti pò ìyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú.
5 On the day of our king the princes made themselves sick with the heat of wine; he joined hands with mockers. Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wa wáìnì mú ara ọmọ-aládé gbóná ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́.
6 For they draw near with hearts burning like an oven as they lie in wait; all night their anger smolders, and in the morning it blazes like a flaming fire. Ọkàn wọn ń gbóná bí i ààrò wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú rìkíṣí, ìbínú wọn pa lọ́lọ́ ní gbogbo òru ó sì bú jáde bí ọ̀wọ́-iná ní òwúrọ̀.
7 They are all hot as an oven, and they devour their rulers. All their kings have fallen; none of them calls upon me. Gbogbo wọn gbóná bí ààrò wọ́n pa gbogbo olórí wọn run, gbogbo ọba wọn si ṣubú kò sì ṣí ẹnìkan nínú wọn tí ó ké pè mí.
8 Ephraim mixes himself among the peoples; Ephraim is a flat cake not turned over. “Efraimu ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà; Efraimu jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà.
9 Strangers devour his strength, and he does not know it; gray hairs are sprinkled upon him, and he does not know it. Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ run ṣùgbọ́n kò sì mọ̀. Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiri bẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsi i.
10 The pride of Israel testifies to his face, yet they do not return to their Father, nor seek him, in all of this. Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí sí i ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a.
11 Ephraim has become like a dove, silly and without sense, calling to Egypt, going to Assyria. “Efraimu dàbí àdàbà tó rọrùn láti tànjẹ àti aláìgbọ́n tó wá ń pé Ejibiti nísinsin yìí tó sì tún ń padà lọ si Asiria.
12 As they go, I will spread my net over them; I will bring them down like the birds of the sky. I will discipline them as their assembly was warned. Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn, Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run. Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀, Èmi ó nà wọ́n fún iṣẹ́ búburú ọwọ́ wọn.
13 Woe to them, for they have strayed from me! Destruction to them, for they have rebelled against me! I would redeem them, but they speak lies against me. Ègbé ní fún wọn, nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun wà lórí wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi! Èmi fẹ́ láti rà wọ́n padà. Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi.
14 They do not cry to me from their heart, but they wail upon their beds; for grain and new wine they gash themselves; they turn away from me. Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùnréré ẹkún lórí ibùsùn wọn. Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnì ṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.
15 Although I trained and strengthened their arms, yet they devise evil against me. Mo kọ́ wọn, mo sì fún wọn ní agbára, síbẹ̀ wọ́n tún ń dìtẹ̀ mọ́ mi.
16 They turn, but not upward; they have become like a slack bow. Their princes will fall by the sword for the insolence of their tongue; this will make them a laughingstock in the land of Egypt. Wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ Ọ̀gá-ògo; wọ́n dàbí ọfà tí ó ti bàjẹ́. Àwọn aṣíwájú wọn yóò ti ipa idà ṣubú nítorí ìrunú ahọ́n wọn. Torí èyí, wọn ó fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ní ilẹ̀ Ejibiti.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]