Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Numbers 34 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 And our Father spoke to Moses, saying, Olúwa sọ fún Mose pé,
2 "command the Israelites: when you enter the land of Canaan, this is the land that will fall to you as inheritance—the land of Canaan, within its borders. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Tí ẹ bá wọ Kenaani, ilẹ̀ tí a ó fi fún yín, gẹ́gẹ́ bí ogún yín yóò ní ààlà wọn yí:
3 Your south side runs from the Zin wilderness along Edom's edge; your south border starts at the Dead Sea's end, eastward. “ ‘Ìhà gúúsù yín yóò bọ́ sí ara aginjù Sini lẹ́bàá Edomu, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà gúúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀,
4 Your border will turn south of the Ascent of Akrabbim, cross to Zin, reach south of Kadesh-barnea, go on to Hazar-addar, and pass to Azmon. kọjá lọ sí gúúsù Akrabbimu, tẹ̀síwájú lọ si Sini, kó bọ́ si gúúsù Kadeṣi-Barnea, kí o sì dé Hasari-Addari, kí o sì kọjá sí Asmoni.
5 From Azmon the border turns to Egypt's Brook, ending at the Sea. Kí òpin ilẹ̀ rẹ̀ kí ó sì yíká láti Asmoni lọ dé odò Ejibiti, Òkun Ńlá ni yóò sì jẹ òpin rẹ.
6 "Your western border will be the Mediterranean Sea and its coast. Ìhà ìwọ̀-oòrùn yín yóò jẹ́ òpin lórí Òkun Ńlá. Èyí yóò jẹ́ ààlà yín lórí ìhà ìwọ̀-oòrùn.
7 "This will be your north border: from the Mediterranean Sea draw your line to Mount Hor. Fún ààlà ìhà àríwá, fa ìlà láti Òkun Ńlá lọ sí orí òkè Hori,
8 From Mount Hor mark a line to Lebo-hamath, ending at Zedad; àti láti orí òkè Hori sí Lebo-Hamati. Nígbà náà ààlà náà yóò lọ sí Sedadi,
9 then the border will extend to Ziphron and end at Hazar-enan. This will be your northern border. tẹ̀síwájú lọ sí Sifroni, kí o sì fò pín si ní Hasari-Enani, èyí yóò jẹ́ ààlà tìrẹ ní ìhà àríwá.
10 "You will mark out your eastern border from Hazar-enan to Shepham. Kí ẹ sì sàmì sí ilẹ̀ tiyín ní ìhà ìlà-oòrùn láti Hasari-Enani lọ dé Ṣefamu.
11 The border will go down from Shepham to Riblah, east of Ain, then go down and reach the slope east of the Sea of Chinnereth. Ààlà náà yóò ti Ṣefamu sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ribla ní ìhà ìlà-oòrùn Aini, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kinnereti ní ìhà ìlà-oòrùn.
12 The border goes down to the Jordan, ending at the Dead Sea. This will be your land, with its borders all around." Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jordani, yóò sì dópin nínú Òkun Iyọ̀. “ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ”
13 Moses commanded the Israelites: This is the land you will inherit by lot, which our Father commanded to give to the nine tribes and the half-tribe. Mose pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: Olúwa ti pàṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án, àti ààbọ̀.
14 The tribe of Reuben's sons, by their fathers' houses, and the tribe of Gad's sons, by their fathers' houses, have already taken their inheritance; so has the half-tribe of Manasseh. Nítorí ará ilẹ̀ ẹ̀yà ti Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ẹ̀yà ààbọ̀ ti Manase ti gba ogún tiwọn.
15 The two and a half tribes received their inheritance across the Jordan from Jericho, eastward toward the sunrise. Ẹ̀yà méjèèjì àti ààbọ̀ yìí ti gba ogún tiwọn ní ìhà ìhín Jordani létí i Jeriko, ní ìhà ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ Jordani.”
16 And our Father spoke to Moses, saying, Olúwa sọ fún Mose pé,
17 "names of the men who will divide the land for you as inheritance: Eleazar the priest and Joshua son of Nun. “Èyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin náà tí yóò pín ilẹ̀, náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ogún: Eleasari àlùfáà àti Joṣua ọmọ Nuni.
18 And you will take one leader from each tribe to divide the land for inheritance. Kí o sì yan olórí kan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti pín ilẹ̀ náà.
19 These are the names of the men: from the tribe of Judah, Caleb the son of Jephunneh; “Èyí ni orúkọ wọn: “Kalebu ọmọ Jefunne, láti ẹ̀yà Juda;
20 from the tribe of the sons of Simeon, Shemuel the son of Ammihud; Ṣemueli ọmọ Ammihudu, láti ẹ̀yà Simeoni;
21 from the tribe of Benjamin, Elidad the son of Chislon; Elidadi ọmọ Kisloni, láti ẹ̀yà Benjamini;
22 from the tribe of the sons of Dan, a leader, Bukki the son of Jogli; Bukki ọmọ Jogli, láti ẹ̀yà olórí àwọn ọmọ Dani;
23 from Joseph's sons: from Manasseh's tribe, leader Hanniel son of Ephod, Hannieli ọmọ Efodu, láti ẹ̀yà Manase, olórí àwọn ọmọ Josẹfu,
24 and from the tribe of the sons of Ephraim, a leader, Kemuel the son of Shiphtan; Kemueli ọmọ Ṣiftani, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ, Efraimu, ọmọ Josẹfu;
25 from the tribe of the sons of Zebulun, a leader, Elizaphan the son of Parnach; Elisafani ọmọ Parnaki, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Sebuluni;
26 from the tribe of the sons of Issachar, a leader, Paltiel the son of Azzan; Paltieli ọmọ Assani, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Isakari;
27 from the tribe of the sons of Asher, a leader, Ahihud the son of Shelomi; Ahihudu ọmọ Ṣelomi, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Aṣeri;
28 and from the tribe of the sons of Naphtali, a leader, Pedahel the son of Ammihud." Pedaheli ọmọ Ammihudu, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Naftali.”
29 These are the ones our Father commanded to divide the inheritance among the children of Israel in the land of Canaan. Èyí ni àwọn ẹni tí Olúwa yàn láti pín ogún náà fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]