Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Numbers 33 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 These are the stages of the Israelites' journey out of Egypt, by their divisions under Moses and Aaron's hand. Wọ̀nyí ni ìrìnàjò àwọn ọmọ Israẹli ní ẹsẹẹsẹ, nígbà tí wọ́n tí ilẹ̀ Ejibiti jáde wá pẹ̀lú àwọn ogun wọn, nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.
2 Moses wrote their starting points by stage, at our Father's command; these are their stages by starting points. Mose sì kọ̀wé ìjáde lọ wọn ní ẹsẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí ìrìnàjò wọn, nípa àṣẹ Olúwa, wọ̀nyí sì ni ìrìnàjò wọn gẹ́gẹ́ bí ìjáde lọ wọn.
3 They set out from Rameses on the fifteenth day of the first month, the day after Passover—the Israelites marched out boldly, in full view of all the Egyptians, Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láti Ramesesi ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ọjọ́ kan lẹ́yìn àjọ ìrékọjá. Wọ́n yan jáde pẹ̀lú ìgboyà níwájú gbogbo àwọn ará Ejibiti.
4 while the Egyptians buried all their firstborn, whom our Father had struck down among them, and on their gods our Father executed judgments. Tí wọ́n sì ń sin gbogbo àkọ́bí wọn, ẹni tí Olúwa ti gbé lulẹ̀ láàrín wọn; nítorí tí Olúwa ti mú ẹ̀san wá sórí àwọn òrìṣà wọn.
5 The children of Israel set out from Rameses and camped at Succoth. Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi wọ́n sì pàgọ́ sí Sukkoti.
6 They set out from Succoth and camped at Etham, which is on the edge of the wilderness. Wọ́n kúrò ní Sukkoti, wọ́n sì pàgọ́ sí Etamu, ní ẹ̀bá aginjù.
7 They left Etham, turned back to Pi-hahiroth, east of Baal-zephon, and camped before Migdol. Wọ́n kúrò ní Etamu, wọ́n padà sí Pi-Hahirotu sí ìlà-oòrùn Baali-Ṣefoni, wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Migdoli.
8 They set out from before Hahiroth, crossed the sea into the wilderness, traveled three days through the wilderness of Etham, and camped at Marah. Wọ́n sì dìde láti lọ kúrò ní iwájú Pi-Hahirotu, wọ́n sì la àárín òkun kọjá lọ sí aginjù. Wọ́n sì rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta ní aginjù Etamu, wọ́n sì pàgọ́ sí Mara.
9 They left Marah and reached Elim, where twelve water springs and seventy palm trees stood; there they camped. Wọ́n kúrò ní Mara wọ́n sì lọ sí Elimu, níbi tí orísun omi méjìlá àti igi ọ̀pẹ àádọ́rin gbé wà, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀.
10 They set out from Elim and camped by Yam Suph. Wọ́n kúrò ní Elimu wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun Pupa.
11 They set out from Yam Suph and camped in the wilderness of Sin. Wọ́n kúrò ní ẹ̀bá Òkun Pupa wọ́n sì pàgọ́ sínú aginjù Sini.
12 They set out from the wilderness of Sin and camped at Dophkah. Wọ́n kúrò nínú aginjù Sini wọ́n sì pàgọ́ sí aginjù Dofka.
13 They set out from Dophkah and camped at Alush. Wọ́n kúrò ní Dofka wọ́n sì pàgọ́ ní Aluṣi.
14 They left Alush and camped at Rephidim, where the people had no water to drink. Wọ́n kúrò ní Aluṣi wọ́n sì pàgọ́ ní Refidimu níbi tí kò sí omi fún àwọn ènìyàn náà láti mu.
15 They set out from Rephidim and camped in the wilderness of Sinai. Wọ́n kúrò ní Refidimu wọ́n sì pàgọ́ ní aginjù Sinai.
16 They set out from the wilderness of Sinai and camped at Kibroth-hattaavah. Wọ́n kúrò ní aginjù Sinai wọ́n sì pàgọ́ ní Kibirotu-Hattaafa.
17 They set out from Kibroth-hattaavah and camped at Hazeroth. Wọ́n kúrò ní Kibirotu-Hattaafa wọ́n sì pàgọ́ ní Haserotu.
18 They set out from Hazeroth and camped at Rithmah. Wọ́n kúrò ní Haserotu wọ́n sì pàgọ́ ní Ritma.
19 They set out from Rithmah and camped at Rimmon-perez. Wọ́n kúrò ní Ritma wọ́n sì pàgọ́ ní Rimoni-Peresi.
20 They set out from Rimmon-perez and camped at Libnah. Wọ́n kúrò ní Rimoni-Peresi wọ́n sì pàgọ́ ní Libina.
21 They set out from Libnah and camped at Rissah. Wọ́n kúrò ní Libina wọ́n sì pàgọ́ ní Rissa.
22 They set out from Rissah and camped at Kehelathah. Wọ́n kúrò ní Rissa wọ́n sì pàgọ́ ní Kehelata.
23 They set out from Kehelathah and camped at Mount Shepher. Wọ́n kúrò ní Kehelata wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Ṣeferi.
24 They set out from Mount Shepher and camped at Haradah. Wọ́n kúrò lórí òkè Ṣeferi wọ́n sì pàgọ́ ní Harada.
25 They set out from Haradah and camped at Makheloth. Wọ́n kúrò ní Harada wọ́n sì pàgọ́ ní Makhelotu.
26 They set out from Makheloth and camped at Tahath. Wọ́n kúrò ní Makhelotu wọ́n sì pàgọ́ ní Tahati.
27 They set out from Tahath and camped at Terah. Wọ́n kúrò ní Tahati wọ́n sì pàgọ́ ní Tẹra.
28 They set out from Terah and camped at Mithkah. Wọ́n kúrò ní Tẹra wọ́n sì pàgọ́ ní Mitka.
29 They set out from Mithkah and camped at Hashmonah. Wọ́n kúrò ní Mitka wọ́n pàgọ́ ní Haṣmona.
30 They set out from Hashmonah and camped at Moseroth. Wọ́n kúrò ní Haṣmona wọ́n sì pàgọ́ ní Moserotu.
31 They set out from Moseroth and camped at Bene-jaakan. Wọ́n kúrò ní Moserotu wọ́n sì pàgọ́ ní Bene-Jaakani.
32 They set out from Bene-jaakan and camped at Hor-haggidgad. Wọ́n kúrò ní Bene-Jaakani wọ́n sì pàgọ́ ní Hori-Haggidgadi.
33 They set out from Hor-haggidgad and camped at Jotbathah. Wọ́n kúrò ní Hori-Haggidgadi wọ́n sí pàgọ́ ní Jotbata.
34 They set out from Jotbathah and camped at Abronah. Wọ́n kúrò ní Jotbata wọ́n sì pàgọ́ ní Abrona.
35 They set out from Abronah and camped at Ezion-geber. Wọ́n kúrò ní Abrona wọ́n sì pàgọ́ ní Esioni-Geberi.
36 They set out from Ezion-geber and camped in the wilderness of Zin, that is, Kadesh. Wọ́n kúrò ní Esioni-Geberi wọ́n sì pàgọ́ ní Kadeṣi nínú aginjù Sini.
37 They left Kadesh and camped at Mount Hor, on the edge of Edom's land. Wọ́n kúrò ní Kadeṣi wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Hori, lẹ́bàá Edomu.
38 Aaron the priest climbed Mount Hor at our Father's command and died there in the fortieth year after the children of Israel left the land of Egypt, in the fifth month, on its first day. Nípa àṣẹ Olúwa, Aaroni àlùfáà gùn orí òkè Hori, níbẹ̀ ni ó kú. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù karùn-ún, ọdún ogójì, lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá.
39 Aaron was 123 years old when he died on Mount Hor. Aaroni jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún ó lé mẹ́ta (123) ní ìgbà tí ó kú sí orí òkè Hori.
40 The Canaanite king of Arad, living in the Negev of Canaan, heard the Israelites were coming. Àwọn ará Kenaani, ọba Aradi, tí ń gbé ìhà gúúsù ní ilẹ̀ Kenaani gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ń bọ̀.
41 They set out from Mount Hor and camped at Zalmonah. Wọ́n kúrò ní orí òkè Hori, wọ́n sì pàgọ́ ní Salmona.
42 They set out from Zalmonah and camped at Punon. Wọ́n kúrò ní Salmona wọ́n sì pàgọ́ ní Punoni.
43 They set out from Punon and camped at Oboth. Wọ́n kúrò ní Punoni wọ́n sì pàgọ́ ní Obotu.
44 They set out from Oboth and camped at Iye-abarim, on the border of Moab. Wọ́n kúrò ní Obotu wọ́n sì pàgọ́ ní Iye-Abarimu, ní agbègbè Moabu.
45 They set out from Iyim and camped at Dibon-gad. Wọ́n kúrò ní Iyimu, wọ́n sì pàgọ́ ní Diboni-Gadi.
46 They set out from Dibon-gad and camped at Almon-diblathaim. Wọ́n kúrò ní Diboni-Gadi wọ́n sì pàgọ́ ní Alimon-Diblataimu.
47 They set out from Almon-diblathaim and camped in the mountains of Abarim, near Nebo. Wọ́n kúrò ní Alimon-Diblataimu wọ́n sì pàgọ́ sí orí òkè Abarimu lẹ́bàá Nebo.
48 They left the mountains of Abarim and camped on the plains of Moab, by the Jordan at Jericho. Wọ́n kúrò ní orí òkè Abarimu wọ́n sì pàgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jordani ní ìkọjá Jeriko.
49 They camped along the Jordan, from Beth-jeshimoth to Abel-shittim, on the plains of Moab. Níbí ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu wọ́n pàgọ́ lẹ́gbẹ́ Jordani láti Beti-Jeṣimoti títí dé Abeli-Ṣittimu.
50 Our Father spoke to Moses in the plains of Moab by the Jordan at Jericho, saying: Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá Jordani, létí Jeriko, Olúwa sọ fún Mose pé,
51 "Speak to the Israelites and tell them: When you cross the Jordan into the land of Canaan. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ní ìgbà tí ẹ̀yin bá ń rékọjá odò Jordani lọ sí Kenaani,
52 Drive out everyone living in the land before you; destroy all their carved images and metal figures, and tear down all their high places. lé gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín. Run gbogbo àwòrán ère wọn àti gbogbo ère dídá wọn, kí ẹ sì wó gbogbo ibi gíga wọn palẹ̀.
53 Possess the land and live in it, for I have given you the land to possess. Ẹ gba ilẹ̀ náà, kí ẹ̀yin sì máa gbé inú rẹ̀, nítorí èmi ti fi ilẹ̀ náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní yín.
54 Divide the land by lot among your clans—more land to larger clans, less to smaller ones. Wherever the lot falls for someone, that becomes theirs. You will inherit by your ancestral tribes. Ẹ̀yin pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú kèké, gẹ́gẹ́ bí ìdílé yín. Fún ọ̀pọ̀ ni kí ẹ̀yin ó fi ilẹ̀ ìní púpọ̀ fún, àti fún díẹ̀, ni kí ẹ̀yin kí ó fi ilẹ̀ ìní díẹ̀ fún. Ohunkóhun tí ó bá bọ́ sí ọ̀dọ̀ wọn nípa kèké yóò jẹ́ tiwọn. Pín wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìran wọn.
55 "But if you don't drive out the land's residents before you, those you leave will be barbs in your eyes and thorns in your sides, troubling you in the land where you live. “ ‘Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá lé àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, àwọn tí ẹ bá jẹ́ kí ó kù yóò di ọfà nínú ojú yín, àti ẹ̀gún ní ìhà yín. Wọn yóò fún yín ní wàhálà ní ilẹ̀ náà tí ẹ̀yin yóò gbé.
56 And then I will do to you what I had planned to do to them." Nígbà náà, èmi yóò ṣe sí yín, ohun tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.’ ”
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]