Skip to content
The Believer's Library

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Isaiah 17 OYCB

Show OYCB only
Verse × ×
1 An oracle about Damascus. Look—Damascus will no longer be a city; it becomes a heap of ruins. Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Damasku: “Kíyèsi i, Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́ ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.
2 The cities of Aroer are abandoned; they will be left for the flocks, which will lie down with no one to frighten them. Àwọn ìlú Aroeri ni a ó kọ̀sílẹ̀ fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn síbẹ̀, láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.
3 The fortress will vanish from Ephraim, and the kingdom from Damascus; and the remnant of Aram will be like the glory of the children of Israel, declares the Father of heaven's armies. Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Efraimu, àti agbára ọba kúrò ní Damasku; àwọn àṣẹ́kù Aramu yóò dá gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Israẹli,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
4 In that day the glory of Jacob will be brought low, and the fat of his body will waste away. “Ní ọjọ́ náà ni ògo Jakọbu yóò sá; ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.
5 It will be as when a harvester gathers the standing grain and harvests the heads of grain with his arm; it will be as when someone gleans the grain in the Valley of Rephaim. Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkórè kó àwọn irúgbìn tí ó dúró jọ tí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀— àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní àfonífojì ti Refaimu.
6 Yet a few will be left, as when an olive tree is beaten: two or three ripe olives at the very top, four or five on the fruitful branches, declares the Father of Israel. Síbẹ̀síbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi olifi, tí èso olifi méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kù sórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ, mẹ́rin tàbí márùn-ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,” ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Israẹli.
7 In that day people will look to their Maker, and their eyes will turn to the Holy One of Israel—our Father. Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójú sókè sí Ẹlẹ́dàá wọn, wọn yóò sì síjú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli.
8 They will not look to the altars, the work of their hands, and they will not gaze at what their own fingers have made—the Asherah poles and the incense altars. Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́, èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn, wọn kò sì ní kọbi ara sí ère Aṣerah mọ́ tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe.
9 In that day their strong cities will be like the abandoned places of the woods and hilltops, which were deserted when the children of Israel came; and it will be a desolation. Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára rẹ̀, yóò dàbí ẹ̀ka ìkọ̀sílẹ̀, àti ẹ̀ka téńté òkè tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.
10 For you have forgotten the Father of your salvation, and you have not remembered the Rock of your refuge. Therefore, though you plant pleasant gardens and set out cuttings from a foreign vine, Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ; tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀.
11 and though on the day you plant them they begin to sprout, and by morning your planting is in blossom, yet the harvest will vanish in a day of grief and incurable pain. Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àṣàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hù jáde, àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n ẹ mú kí wọ́n rúdí, síbẹ̀síbẹ̀ ìkórè kò ní mú nǹkan wá ní ọjọ́ ààrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.
12 Ah, the uproar of many peoples—they roar like the roaring of the seas! The rumbling of nations—they rumble like the rumbling of mighty waters! Kíyèsi i, ìrunú àwọn orílẹ̀-èdè— wọ́n ń runú bí ìgbì Òkun! Kíyèsi i, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!
13 The nations rumble like the rumbling of many waters, but our Father will rebuke them, and they will flee far away, driven before the wind like chaff on the hills, like whirling dust before the storm. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò, nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n sálọ jìnnà réré, a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè, àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.
14 At evening, sudden terror! Before morning, they are gone. This is the portion of those who plunder us, the lot of those who loot us. Ní aginjù, ìpayà òjijì! Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́! Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù, àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa.
FHB

Scripture from Father’s Heart Bible™. © 2026 Spirit Media Publishing, the imprint of Spirit Media Inc. All rights reserved. In Divine Voice™ Color, the words spoken by our Father show in blue, the words of the Son in red, and the words of the Spirit in purple.

OYCB

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. ‪“Biblica” ni àmì ìdámọ̀ tí Biblica, Inc. fi sílẹ̀ ní United States Patent àti ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fúnni ní àmì ìdámọ̀. Gba àṣẹ kí o tó lòó. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission.
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 · Creative Commons - Attribution-ShareAlike [CC BY-SA]